26. Nitori eyiyi li Ọlọrun ṣe fi wọn fun ifẹ iwakiwa: nitori awọn obinrin wọn tilẹ yi ilo ẹda pada si eyi ti o lodi si ẹda:
27. Gẹgẹ bẹ̃ li awọn ọkunrin pẹlu, nwọn a mã fi ilò obinrin nipa ti ẹda silẹ, nwọn a mã ni ifẹkufẹ gbigbona si ara wọn; ọkunrin mba ọkunrin ṣe eyi ti kò yẹ, nwọn si njẹ ère ìṣina wọn ninu ara wọn bi o ti yẹ si.
28. Ati gẹgẹ bi nwọn ti kọ̀ lati ni ìro Ọlọrun ni ìmọ wọn, Ọlọrun fi wọn fun iyè rirà lati ṣe ohun ti kò tọ́:
29. Nwọn kún fun aiṣododo gbogbo, àgbere, ìka, ojukòkoro, arankan; nwọn kún fun ilara, ipania, ija, itanjẹ, iwa-buburu; afi-ọrọ-kẹlẹ banijẹ,
30. Asọrọ ẹni lẹhin, akorira Ọlọrun, alafojudi, agberaga, ahalẹ, alaroṣe ohun buburu, aṣaigbọran si obí,