14. O sa joko li ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀, lori apoti, ni ibi giga ilu.
15. Lati ma pè awọn ti nkọja nibẹ, ti nrìn ọ̀na ganran wọn lọ: pe,
16. Ẹnikẹni ti o ba ṣe òpe, ki o yà si ìhin: ẹniti oye kù fun, o wi fun u pe,
17. Omi ole dùn, ati onjẹ ikọkọ si ṣe didùn.
18. Ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn okú wà nibẹ: ati pe awọn alapejẹ rẹ̀ wà ni isalẹ ọrun-apadi.