10. Awọn enia-ẹ̀jẹ korira aduro-ṣinṣin: ṣugbọn awọn olododo a ma ṣe afẹri ọkàn rẹ̀.
11. Aṣiwère a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọ́n a pa a mọ́ di ìgba ikẹhin.
12. Bi ijoye ba feti si ọ̀rọ-eke, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ni yio buru.
13. Talaka ati aninilara enia pejọ pọ̀: Oluwa li o ntan imọlẹ si oju awọn mejeji.
14. Ọba ti o fi otitọ ṣe idajọ talaka, itẹ́ rẹ̀ yio fi idi mulẹ lailai.
15. Paṣan ati ibawi funni li ọgbọ́n: ṣugbọn ọmọ ti a ba jọwọ rẹ̀ fun ara rẹ̀, a dojuti iya rẹ̀.
16. Nigbati awọn enia buburu ba npọ̀ si i, irekọja a pọ̀ si i: ṣugbọn awọn olododo yio ri iṣubu wọn.
17. Tọ́ ọmọ rẹ, yio si fun ọ ni isimi; yio si fi inu-didùn si ọ li ọkàn.
18. Nibiti iran-woli kò si, enia a yapa, ṣugbọn ibukún ni fun ẹniti o pa ofin mọ́.
19. A kì ifi ọ̀rọ kilọ fun ọmọ-ọdọ; bi o tilẹ ye e kì yio dahùn.
20. Iwọ ri enia ti o yara li ọ̀rọ rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.
21. Ẹniti o ba fi ikẹ́ tọ́ ọmọ-ọdọ rẹ̀ lati igba-ewe wá, oun ni yio jogún rẹ̀.
22. Ẹni ibinu ru ìja soke, ati ẹni ikannu pọ̀ ni irekọja.
23. Igberaga enia ni yio rẹ̀ ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹ ọkàn ni yio gbà ọlá.
24. Ẹniti o kó ẹgbẹ ole korira ọkàn ara rẹ̀: o ngbọ́ ifiré, kò si fihan.
25. Ibẹ̀ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o gbe leke.
26. Ọpọlọpọ enia li o nwá ojurere ijoye: ṣugbọn idajọ enia li o nti ọdọ Oluwa wá.
27. Alaiṣõtọ enia, irira ni si awọn olododo: ẹniti o si ṣe aduro-ṣinṣin li ọ̀na, irira ni si enia buburu.