4. Ọrọ̀ kì ini anfani li ọjọ ibinu: ṣugbọn ododo ni igbani lọwọ ikú.
5. Ododo ẹni-pipé yio ma tọ́ ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu ninu ìwa-buburu rẹ̀.
6. Ododo awọn aduro-ṣinṣin yio gbà wọn là: ṣugbọn awọn olurekọja li a o mu ninu iṣekuṣe wọn:
7. Nigbati enia buburu ba kú, ireti rẹ̀ a dasan, ireti awọn alaiṣedede enia a si dasan.
8. A yọ olododo kuro ninu iyọnu, enia buburu a si bọ si ipò rẹ̀.
9. Ẹnu li agabagebe ifi pa aladugbo rẹ̀: ṣugbọn ìmọ li a o fi gbà awọn olododo silẹ.
10. Nigbati o ba nṣe rere fun olododo, ilu a yọ̀: nigbati enia buburu ba ṣegbe, igbe-ayọ̀ a ta.
11. Nipa ibukún aduro-ṣinṣin ilu a gbé lèke: ṣugbọn a bì i ṣubu nipa ẹnu enia buburu.
12. Ẹniti oye kù fun gàn ọmọnikeji rẹ̀; ṣugbọn ẹni oye a pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
13. Ẹniti nṣofofo fi ọ̀ran ipamọ́ hàn; ṣugbọn ẹniti nṣe olõtọ-ọkàn a pa ọ̀rọ na mọ́.
14. Nibiti ìgbimọ kò si, awọn enia a ṣubu; ṣugbọn ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni ailewu.
15. Ẹniti o ba ṣe onigbọwọ fun alejo, ni yio ri iyọnu; ẹniti o ba si korira iṣegbọwọ wà lailewu.
16. Obinrin olore-ọfẹ gbà iyìn: bi alagbara enia ti igbà ọrọ̀.
17. Alãnu enia ṣe rere fun ara rẹ̀: ṣugbọn ìka-enia nyọ ẹran-ara rẹ̀ li ẹnu.
18. Enia buburu nṣiṣẹ ère-ẹ̀tan; ṣugbọn ẹniti ngbin ododo ni ère otitọ wà fun.