Owe 1:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ̀ ba tàn ọ, iwọ má ṣe gbà.

11. Bi nwọn wipe, Wá pẹlu wa, jẹ ki a ba fun ẹ̀jẹ, jẹ ki a lugọ ni ikọkọ de alaiṣẹ̀ lainidi.

12. Jẹ ki a gbe wọn mì lãye bi isà-okú; ati awọn ẹni-diduroṣinṣin bi awọn ti nlọ sinu iho:

13. Awa o ri onirũru ọrọ̀ iyebiye, awa o fi ikogun kún ile wa:

14. Dà ipin rẹ pọ̀ mọ arin wa; jẹ ki gbogbo wa ki a jọ ni àpo kan:

15. Ọmọ mi, máṣe rìn li ọ̀na pẹlu wọn: fà ẹsẹ rẹ sẹhin kuro ni ipa-ọ̀na wọn.

16. Nitori ti ẹsẹ wọn sure si ibi, nwọn si yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ.

17. Nitõtọ, lasan li a nà àwọn silẹ li oju ẹiyẹkẹiyẹ.

Owe 1