Oni 9:6-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ifẹ wọn pẹlu, ati irira wọn, ati ilara wọn, o parun nisisiyi; bẹ̃ni nwọn kò si ni ipin mọ lailai ninu ohun gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn.

7. Ma ba tirẹ lọ, ma fi ayọ̀ jẹ onjẹ rẹ, ki o si mã fi inu-didun mu ọti-waini rẹ: nitoripe Ọlọrun tẹwọgba iṣẹ rẹ nisisiyi.

8. Jẹ ki aṣọ rẹ ki o ma fún nigbagbogbo; ki o má si jẹ ki ori rẹ ki o ṣe alaini ororo ikunra,

9. Ma fi ayọ̀ ba aya rẹ gbe ti iwọ fẹ ni gbogbo ọjọ aiye asan rẹ, ti o fi fun ọ labẹ õrùn ni gbogbo ọjọ asan rẹ: nitori eyini ni ipin tirẹ li aiye yi, ati ninu lãla ti iwọ ṣe labẹ õrùn.

10. Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e; nitoriti kò si ete, bẹ̃ni kò si ìmọ, tabi ọgbọ́n, ni isa-okú nibiti iwọ nrè.

11. Mo pada, mo si ri labẹ õrùn, pe ire-ije kì iṣe ti ẹniti o yara, bẹ̃li ogun kì iṣe ti alagbara, bẹ̃li onjẹ kì iṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ̃li ọrọ̀ kì iṣe ti ẹni oye, bẹ̃li ojurere kì iṣe ti ọlọgbọ́n-inu; ṣugbọn ìgba ati eṣe nṣe si gbogbo wọn.

Oni 9