1. NIBO ni olufẹ rẹ lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? nibo li olufẹ rẹ yà si? ki a le ba ọ wá a.
2. Olufẹ mi sọkalẹ lọ sinu ọgba rẹ̀, si ebè turari, lati ma jẹ̀ ninu ọgbà, ati lati ká itanna lili.
3. Emi ni ti olufẹ mi, olufẹ mi si ni ti emi: o njẹ̀ lãrin itanna lili.
4. Iwọ yanju, olufẹ mi, bi Tirsa, o li ẹwà bi Jerusalemu, ṣugbọn o li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun.
5. Mu oju rẹ kuro lara mi nitori nwọn bori mi: irun rẹ si dabi ọwọ́ ewurẹ ti o dubulẹ ni Gileadi.
6. Ehin rẹ dabi ọwọ́ agutan ti ngòke lati ibi iwẹ̀ wá, ti olukuluku wọn bi ìbejì, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn.