O. Sol 1:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Emi dú, ṣugbọn mo li ẹwà, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi awọn agọ Kedari, bi awọn aṣọ-tita Solomoni.

6. Máṣe wò mi, nitori pe mo dú, nitori pe õrùn ti bojuwò mi: awọn ọmọ iyá mi binu si mi; nwọn fi mi ṣe oluṣọ ọgba-ajara; ṣugbọn ọgba-ajara temi li emi kò tọju.

7. Wi fun mi, Iwọ ẹniti ọkàn mi fẹ, nibiti iwọ nṣọ agutan; nibiti iwọ nmu agbo-ẹran rẹ simi li ọsan; ki emi ki o má ba dabi alãrẹ̀ ti o ṣina kiri pẹlu agbo-ẹran awọn ẹgbẹ́ rẹ.

8. Bi iwọ kò ba mọ̀, Iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin, jade lọ ni ipasẹ agbo-ẹran, ki iwọ ki o si bọ́ awọn ọmọ ewurẹ rẹ lẹba agọ awọn aluṣọ-agutan.

9. Olufẹ mi, mo ti fi ọ we ẹṣin mi ninu kẹkẹ́ Farao.

10. Ẹrẹkẹ́ rẹ li ẹwà ninu ọwọ́ ohun ọṣọ́, ọrùn rẹ ninu ilẹkẹ.

O. Sol 1