O. Daf 69:34-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. Jẹ ki ọrun on aiye ki o yìn i, okun ati ohun gbogbo ti nrakò ninu wọn.

35. Nitoriti Ọlọrun yio gbà Sioni là, yio si kọ́ ilu Juda wọnni: ki nwọn ki o le ma gbe ibẹ, ki nwọn ki o le ma ni i ni ilẹ-ini.

36. Iru-ọmọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ni yio ma jogun rẹ̀: awọn ti o si fẹ orukọ rẹ̀ ni yio ma gbe inu rẹ̀.

O. Daf 69