1. ẸNYIN ha nsọ ododo nitõtọ, ẹnyin ijọ enia? ẹnyin ha nṣe idajọ ti o ṣe titọ, ẹnyin ọmọ enia?
2. Nitõtọ, ẹnyin nṣiṣẹ buburu li aiya; ẹnyin nwọ̀n ìwa-agbara ọwọ nyin li aiye.
3. Lati inu iya wọn wá li awọn enia buburu ti ṣe iyapa: nwọn ti ṣina lojukanna ti a ti bi wọn, nwọn a ma ṣeke.