9. Awọn ọmọbinrin awọn alade wà ninu awọn ayanfẹ rẹ: li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri.
10. Dẹti silẹ, ọmọbinrin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ!
11. Bẹ̃li Ọba yio fẹ ẹwà rẹ gidigidi: nitori on li Oluwa rẹ; ki iwọ ki o si ma sìn i.
12. Ọmọbinrin Tire ti on ti ọrẹ; ati awọn ọlọrọ̀ ninu awọn enia yio ma bẹ̀bẹ oju-rere rẹ.
13. Ti ogo ti ogo li ọmọbinrin ọba na ninu ile: iṣẹ wura ọnà abẹrẹ li aṣọ rẹ̀.
14. Ninu aṣọ iṣẹ ọnà abẹrẹ li a o mu u tọ̀ ọba wá: awọn wundia, ẹgbẹ rẹ̀ ti ntọ̀ ọ lẹhin li a o mu tọ̀ ọ wá.
15. Pẹlu inu didùn ati pẹlu ayọ̀ li a o fi mu wọn wá: nwọn o si wọ̀ ãfin ọba lọ.
16. Nipò awọn baba rẹ li awọn ọmọ rẹ yio wà, ẹniti iwọ o ma fi jẹ oye lori ilẹ gbogbo.
17. Emi o ma ṣe orukọ rẹ ni iranti ni iran gbogbo: nitorina li awọn enia yio ṣe ma yìn ọ lai ati lailai.