9. Emi ti wãsu ododo ninu awujọ nla: kiyesi i, emi kò pa ete mi mọ́, Oluwa, iwọ mọ̀.
10. Emi kò fi ododo rẹ sin li aiya mi, emi o sọ̀rọ otitọ ati igbala rẹ: emi kò si pa iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ mọ́ kuro lọdọ ijọ nla nì.
11. Iwọ máṣe fa ãnu rẹ ti o rọnu sẹhin kuro lọdọ mi, Oluwa: ki iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ ki o ma pa mi mọ́ nigbagbogbo.
12. Nitoripe ainiye ibi li o yika kiri: ẹ̀ṣẹ mi dì mọ mi, bẹ̃li emi kò le gbé oju wò oke, nwọn jù irun ori mi lọ: nitorina aiya mi npá mi.
13. Ki o wù ọ, Oluwa, lati gbà mi: Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ,
14. Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si damu pọ̀, awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run; ki a lé wọn pada sẹhin, ki a si dojuti awọn ti nfẹ mi ni ibi.
15. Ki nwọn ki o di ofo fun ère itiju wọn, awọn ti nwi fun mi pe, A! a!
16. Ki gbogbo awọn ti nwá ọ, ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn sipa tirẹ: ki gbogbo awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Gbigbega li Oluwa.
17. Ṣugbọn talaka ati alaini li emi; Oluwa si nṣe iranti mi; iwọ ni iranlọwọ mi ati olugbala mi: máṣe pẹ titi, Ọlọrun mi.