5. Ki nwọn ki o dabi iyangbo niwaju afẹfẹ: ki angeli Oluwa ki o ma le wọn.
6. Ki ọ̀na wọn ki o ṣokunkun ki o si ma yọ́; ki angeli Oluwa ki o si ma lepa wọn.
7. Nitori pe, li ainidi ni nwọn dẹ àwọn wọn silẹ fun mi, nwọn wà iho silẹ fun ọkàn mi li ainidi.
8. Ki iparun ki o wá si ori rẹ̀ li ojiji; àwọn rẹ̀ ti o dẹ, ki o mu on tikararẹ̀: iparun na ni ki o ṣubu si.
9. Ọkàn mi yio si ma yọ̀ niti Oluwa: yio si ma yọ̀ ninu igbala rẹ̀.
10. Gbogbo egungun mi ni yio wipe, Oluwa, tali o dabi iwọ, ti ngbà talaka lọwọ awọn ti o lagbara jù u lọ, ani talaka ati alaini lọwọ ẹniti nfi ṣe ikogun?
11. Awọn ẹlẹri eke dide; nwọn mbi mi li ohun ti emi kò mọ̀.
12. Nwọn fi buburu san ore fun mi, lati sọ ọkàn mi di ofo.
13. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, nigbati ara wọn kò dá, aṣọ àwẹ li aṣọ mi: mo fi àwẹ rẹ̀ ọkàn mi silẹ; adura mi si pada si mi li aiya.
14. Emi ṣe ara mi bi ẹnipe ọrẹ tabi arakunrin mi tilẹ ni: emi fi ibinujẹ tẹriba, bi ẹniti nṣọ̀fọ iya rẹ̀.
15. Ṣugbọn ninu ipọnju mi nwọn yọ̀, nwọn si kó ara wọn jọ: awọn enia-kenia kó ara wọn jọ si mi, emi kò si mọ̀; nwọn fa mi ya, nwọn kò si dakẹ.