18. Ẹsẹ ẹniti nwọn fi ṣẹkẹṣẹkẹ pa lara: a dè e ninu irin:
19. Titi igba ti ọ̀rọ rẹ̀ de: ọ̀rọ Oluwa dan a wò.
20. Ọba ranṣẹ, nwọn si tú u silẹ; ani ijoye awọn enia, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.
21. O fi jẹ oluwa ile rẹ̀, ati ijoye gbogbo ini rẹ̀.
22. Lati ma ṣe akoso awọn ọmọ-alade rẹ̀ nipa ifẹ rẹ̀; ati lati ma kọ́ awọn igbimọ rẹ̀ li ọgbọ́n.
23. Israeli si wá si Egipti pẹlu; Jakobu si ṣe atipo ni ilẹ Hamu.
24. O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ.
25. O yi wọn li aiya pada lati korira awọn enia rẹ̀, lati ṣe arekereke si awọn iranṣẹ rẹ̀.