6. Mose si gbà kẹkẹ́-ẹrù wọnni, ati akọmalu, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi.
7. Kẹkẹ́-ẹrù meji ati akọmalu mẹrin, li o fi fun awọn ọmọ Gerṣoni, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn:
8. Ati kẹkẹ́-ẹrù mẹrin ati akọmalu mẹjọ li o fi fun awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn, li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.
9. Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù.
10. Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na.
11. OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ.
12. Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda.
13. Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
14. Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
15. Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
16. Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;