1. OSI ṣe li ọjọ́ na ti Mose gbé agọ́ na ró tán, ti o si ta oróro si i ti o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ na ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ti o si ta oróro si wọn, ti o si yà wọn simimọ́;
2. Ni awọn ijoye Israeli, awọn olori ile baba wọn, awọn olori ẹ̀ya wọnni, ti iṣe olori awọn ti a kà, mú ọrẹ wá:
3. Nwọn si mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju OLUWA, kẹkẹ́-ẹrù mẹfa ti a bò, ati akọmalu mejila; kẹkẹ́-ẹrù kan fun ijoye meji, ati akọmalu kan fun ọkọkan: nwọn si mú wọn wá siwaju agọ́ ajọ.
4. OLUWA si sọ fun Mose pe,
5. Gbà a lọwọ wọn, ki nwọn ki o le jẹ́ ati fi ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ; ki iwọ ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀.
6. Mose si gbà kẹkẹ́-ẹrù wọnni, ati akọmalu, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi.
7. Kẹkẹ́-ẹrù meji ati akọmalu mẹrin, li o fi fun awọn ọmọ Gerṣoni, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn:
8. Ati kẹkẹ́-ẹrù mẹrin ati akọmalu mẹjọ li o fi fun awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn, li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.
9. Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù.
10. Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na.
11. OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ.
12. Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda.
13. Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
14. Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
15. Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;