21. Nigbana ni ki alufa ki o mu ki obinrin na fi èpe bura, ki alufa ki o si wi fun obinrin na pe, Ki OLUWA ki o sọ ọ di ẹni egún, ati ẹni ifire ninu awọn enia rẹ, nigbati OLUWA ba mu itan rẹ rà, ti o si mu inu rẹ wú;
22. Ati omi yi ti nmú egún wá ki o wọ̀ inu rẹ lọ, lati mu inu rẹ wú, ati lati mu itan rẹ rà: ki obinrin na ki o si wipe, Amin, amin.
23. Ki alufa ki o si kọ egún yi sinu iwé, ki o si fi omi kikorò na wẹ̀ ẹ nù:
24. Ki o si jẹ ki obinrin na ki o mu omi kikorò na ti imú egún wá: omi na ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò.
25. Nigbana li alufa yio gbà ẹbọ ohunjijẹ owú na li ọwọ́ obinrin na, yio si fì ẹbọ ohunjijẹ na niwaju OLUWA, yio si ru u lori pẹpẹ:
26. Ki alufa ki o si bù ikunwọ kan ninu ẹbọ ohunjijẹ na, ani iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ, lẹhin eyinì ki o jẹ ki obinrin na mu omi na.