Num 4:8-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ki nwọn ki o si nà aṣọ ododó bò wọn, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò o, ki nwọn ki o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.

9. Ki nwọn ki o si mú aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi bò ọpá-fitila nì, ati fitila rẹ̀, ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo oróro rẹ̀, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ rẹ̀.

10. Ki nwọn ki o si fi on ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀ sinu awọ seali, ki nwọn ki o si gbé e lé ori igi.

11. Ati lori pẹpẹ wurà ni ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, nwọn o si fi awọ seali bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.

12. Ki nwọn ki o si kó gbogbo ohunèlo ìsin, ti nwọn fi nṣe iṣẹ-ìsin ninu ibi-mimọ́, ki nwọn ki o si fi wọn sinu aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò wọn, ki nwon ki o si fi wọn kà ori igi.

13. Ki nwọn ki o si kó ẽru kuro lori pẹpẹ, ki nwọn ki o si nà aṣọ elesè-aluko kan bò o.

14. Ki nwọn ki o si fi gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ti nwọn fi ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀ sori rẹ̀, awo iná, ati kọkọrọ ẹran, ati ọkọ́-ẽru, ati awokòto, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na; ki nwọn ki o si nà awọ seali sori rẹ̀, ki nwọn ki o si tẹ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.

15. Nigbati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ba pari ati bò ibi-mimọ́ na tán, ati gbogbo ohun-èlo ibi-mimọ́ na, nigbati ibudó yio ba ṣí siwaju; lẹhin eyinì, li awọn ọmọ Kohati yio wá lati gbé e: ṣugbọn nwọn kò gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ́ kan, ki nwọn ki o má ba kú. Wọnyi li ẹrù awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ.

16. Ohun itọju Eleasari ọmọ Aaroni alufa si ni oróro fitila, ati turari didùn, ati ẹbọ ohunjijẹ ìgbagbogbo, ati oróro itasori, ati itọju agọ́ na gbogbo, ati ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ninu ibi-mimọ́ nì, ati ohun-èlo rẹ̀ na.

17. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,

18. Ẹ máṣe ke ẹ̀ya idile awọn ọmọ Kohati kuro lãrin awọn ọmọ Lefi:

19. Ṣugbọn bayi ni ki ẹ ṣe fun wọn, ki nwọn ki o le yè, ki nwọn ki o má ba kú, nigbati nwọn ba sunmọ ohun mimọ́ julọ: ki Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wọnú ilé, ki nwọn si yàn wọn olukuluku si iṣẹ rẹ̀ ati si ẹrù rẹ̀;

20. Ṣugbọn nwọn kò gbọdọ wọle lọ lati wò ohun mimọ́ ni iṣẹju kan, ki nwọn ki o má ba kú.

21. OLUWA si sọ fun Mose pe,

22. Kà iye awọn ọmọ Gerṣoni pẹlu, gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn;

23. Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki o kaye wọn; gbogbo awọn ti o wọnu-ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.

Num 4