Num 36:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN baba àgba ti idile awọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile awọn ọmọ Josefu, sunmọtosi, nwọn si sọ niwaju Mose, ati niwaju awọn olori, awọn baba àgba awọn ọmọ Israeli:

2. Nwọn si wipe, OLUWA ti paṣẹ fun oluwa mi lati fi keké pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli ni iní: a si fi aṣẹ fun oluwa mi lati ọdọ OLUWA wá lati fi ilẹiní Selofehadi arakunrin wa fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.

3. Bi a ba si gbé wọn niyawo fun ẹnikan ninu awọn ọmọkunrin ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli miran, nigbana ni a o gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní awọn baba wa, a o si fi kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà a kuro ninu ipín ilẹ-iní ti wa.

Num 36