Nwọn si wipe, OLUWA ti paṣẹ fun oluwa mi lati fi keké pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli ni iní: a si fi aṣẹ fun oluwa mi lati ọdọ OLUWA wá lati fi ilẹiní Selofehadi arakunrin wa fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.