Num 33:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Bi awọn ara Egipti ti nsinkú gbogbo awọn akọ́bi wọn ti OLUWA kọlù ninu wọn: lara awọn oriṣa wọn pẹlu li OLUWA ṣe idajọ.

5. Awọn ọmọ Israeli si ṣí kuro ni Ramesesi, nwọn si dó si Sukkotu.

6. Nwọn si ṣí kuro ni Sukkotu, nwọn si dó si Etamu, ti mbẹ leti aginjù.

7. Nwọn si ṣí kuro ni Etamu, nwọn si pada lọ si Pi-hahirotu, ti mbẹ niwaju Baali-sefoni: nwọn si dó siwaju Migdolu.

8. Nwọn si ṣí kuro niwaju Hahirotu, nwọn si là ãrin okun já lọ si aginjù: nwọn si rìn ìrin ijọ́ mẹta li aginjù Etamu, nwọn si dó si Mara.

Num 33