Num 33:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI ni ìrin awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá pẹlu awọn ogun wọn, nipa ọwọ́ Mose ati Aaroni.

2. Mose si kọwe ijadelọ wọn gẹgẹ bi ìrin wọn, nipa aṣẹ OLUWA; wọnyi si ni ìrin wọn gẹgẹ bi ijadelọ wọn.

3. Nwọn si ṣí kuro ni Ramesesi li oṣù kini, ni ijọ́ kẹdogun oṣù kini na; ni ijọ́ keji ajọ irekọja li awọn ọmọ Israeli jade pẹlu ọwọ́ giga li oju gbogbo awọn ara Egipti.

Num 33