13. Ti Sera, idile Sera: ti Ṣaulu, idile Ṣaulu.
14. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Simeoni, ẹgba mọkanla o le igba.
15. Awọn ọmọ Gadi bi idile wọn: ti Sefoni, idile Sefoni: ti Haggi, idile Haggi: ti Ṣuni, idile Ṣuni:
16. Ti Osni, idile Osni: ti Eri, idile Eri:
17. Ti Arodu, idile Arodu: ti Areli, idile Areli.
18. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta.
19. Awọn ọmọ Juda, ni Eri ati Onani: ati Eri ati Onani kú ni ilẹ Kenaani.