Num 10:10-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Li ọjọ̀ ayọ̀ nyin pẹlu, ati li ajọ nyin, ati ni ìbẹrẹ oṣù nyin, ni ki ẹnyin ki o fun ipè sori ẹbọ sisun nyin, ati sori ẹbọ ti ẹbọ alafia nyin; ki nwọn ki o le ma ṣe iranti fun nyin niwaju Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.

11. O si ṣe li ogun ọjọ́ oṣù keji, li ọdún keji, ni awọsanma ká soke kuro lori agọ́ ẹrí.

12. Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati ijù Sinai; awọsanma na si duro ni ijù Parani.

13. Nwọn si bẹ̀rẹsi iṣí gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.

14. Ọpágun ibudó awọn ọmọ Juda si kọ́ ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Naṣoni ọmọ Amminadabu.

15. Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari si ni Netaneli ọmọ Suari.

16. Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni.

17. A si tú agọ́ na palẹ; awọn ọmọ Gerṣoni, ati awọn ọmọ Merari ti nrù agọ́ si ṣí.

18. Ọpágun ibudó Reubeni si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuri ọmọ Ṣedeuri si li olori ogun rẹ̀.

19. Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai

20. Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli.

Num 10