Mik 1:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Mika ara Moraṣti wá li ọjọ Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ti o ri niti Samaria ati Jerusalemu.

2. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹnyin enia; fetisilẹ, Iwọ ilẹ aiye, ati ẹkún rẹ̀: si jẹ ki Oluwa Ọlọrun ṣe ẹlẹri si nyin, Oluwa lati inu tempili mimọ́ rẹ̀ wá.

3. Nitori, wo o, Oluwa jade lati ipò rẹ̀ wá, yio si sọ̀kalẹ, yio si tẹ̀ awọn ibi giga aiye mọlẹ.

4. Awọn oke nla yio si yọ́ labẹ rẹ̀, awọn afonifojì yio si pinyà, bi ida niwaju iná, bi omi ti igbálọ ni ibi gẹ̀rẹgẹ̀rẹ.

5. Nitori irekọja Jakobu ni gbogbo eyi, ati nitori ẹ̀ṣẹ ile Israeli. Kini irekọja Jakobu? Samaria ha kọ? ki si ni awọn ibi giga Juda? Jerusalemu ha kọ?

Mik 1