Mat 5:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI o si ri ọ̀pọ enia, o gùn ori òke lọ: nigbati o si joko, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá.

2. O si yà ẹnu rẹ̀, o si kọ́ wọn, wipe,

3. Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmí: nitori tiwọn ni ijọba ọrun.

4. Alabukún-fun li awọn ẹniti nkãnu: nitoriti a ó tù wọn ninu.

5. Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye.

Mat 5