5. Nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn ó si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ.
6. Ẹnyin o si gburo ogun ati idagìri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹnyin ki o máṣe jaiyà: nitori gbogbo nkan wọnyi ko le ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin ki iṣe isisiyi.
7. Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: ìyan, ati ajakalẹ-arùn, ati iṣẹlẹ̀ yio si wà ni ibi pipọ.
8. Gbogbo nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju.
9. Nigbana ni nwọn o fi nyin funni lati jẹ ni ìya, nwọn o si pa nyin: a o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ède nitori orukọ mi.
10. Nigbana li ọ̀pọlọpọ yio kọsẹ̀, nwọn o si ma ṣòfofo ara wọn, nwọn o si mã korira ara wọn.
11. Wolĩ eke pipọ ni yio si dide, nwọn o si tàn ọpọlọpọ jẹ.
12. Ati nitori ẹ̀ṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù.
13. Ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na li a o gbalà.
14. A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de.
15. Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu wolĩ Danieli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ́, (ẹniti o ba kà a, ki òye ki o yé e:)
16. Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sálọ si ori òke:
17. Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o maṣe sọkalẹ wá imu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀:
18. Ki ẹniti mbẹ li oko maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀.
19. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni!
20. Ẹ si mã gbadura ki sisá nyin ki o máṣe jẹ igba otutù, tabi ọjọ isimi:
21. Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹ̃kọ, irú rẹ̀ kì yio si si.