13. Nitorina li o wi fun ọkunrin na pe, Na ọwọ́ rẹ, on si nà a; ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò rẹ̀ gẹgẹ bi ekeji.
14. Nigbana li awọn Farisi jade lọ, nwọn si gbìmọ nitori rẹ̀, bi awọn iba ti ṣe pa a.
15. Nigbati Jesu ṣi mọ̀, o yẹ̀ ara rẹ̀ kuro nibẹ̀; ọ̀pọ ijọ enia tọ̀ ọ lẹhin, o si mu gbogbo wọn larada.
16. O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn:
17. Ki eyi ti a ti ẹnu wolĩ Isaiah wi ki o ba le ṣẹ, pe,
18. Wo iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi: Emi o fi ẹmí mi fun u, yio si fi idajọ hàn fun awọn keferi.
19. On kì yio jà, kì yio si kigbe; bẹ̃li ẹnikẹni kì yio gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro.