12. Nwọn si jade lọ, nwọn si wasu ki awọn enia ki o le ronupiwada.
13. Nwọn si lé ọ̀pọ awọn ẹmi èṣu jade, nwọn si fi oróro kùn ọ̀pọ awọn ti ara wọn ṣe alaida, nwọn si mu wọn larada.
14. Herodu ọba si gburo rẹ̀; (nitoriti okikí orukọ rẹ̀ kàn yiká:) o si wipe, Johanu Baptisti jinde kuro ninu oku, nitorina ni iṣẹ agbara ṣe nṣe lati ọwọ rẹ̀ wá.
15. Awọn ẹlomiran wipe, Elijah ni. Ṣugbọn awọn miran wipe, Woli kan ni, tabi bi ọkan ninu awọn woli.
16. Ṣugbọn nigbati Herodu gbọ́, o wipe, Johanu ni, ẹniti mo ti bẹ́ lori: on li o jinde kuro ninu okú.
17. Herodu tikararẹ̀ sá ti ranṣẹ mu Johanu, o si dè e sinu tubu nitori Herodia, aya Filippi arakunrin rẹ̀: on sá ti fi i ṣe aya.