Mak 4:30-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. O si wipe, Kili a o fi ijọba Ọlọrun we? tabi kili a ba fi ṣe akawe rẹ̀?

31. O dabi wóro irugbin mustardi, eyiti, nigbati a gbin i si ilẹ, bi o tilẹ ṣe pe o kére jù gbogbo irugbin ti o wa ni ilẹ lọ,

32. Sibẹ nigbati a gbin i o dàgba soke, o si di titobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si pa ẹká nla; tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun le ma gbe abẹ ojiji rẹ̀.

33. Irù ọ̀pọ owe bẹ̃ li o fi mba wọn nsọ̀rọ, niwọn bi nwọn ti le gbà a si.

34. Ṣugbọn on kì iba wọn sọrọ laìsi owe: nigbati o ba si kù awọn nikan, on a si sọ idi ohun gbogbo fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

35. Ni ijọ kanna, nigbati alẹ lẹ tan, o wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a rekọja lọ si apá keji.

36. Nigbati nwọn si ti tu ijọ ká, nwọn si gbà a gẹgẹ bi o ti wà sinu ọkọ̀. Awọn ọkọ̀ kekere miran pẹlu si wà lọdọ rẹ̀.

37. Ìji nla si dide, ìgbi si mbù sinu ọkọ̀, tobẹ̃ ti ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ si ikún.

38. On pãpã si wà ni idi ọkọ̀, o nsùn lori irọri: nwọn si jí i, nwọn si wi fun u pe, Olukọni, iwọ ko bikita bi awa ṣegbé?

39. O si ji, o ba afẹfẹ na wi, o si wi fun okun pe, Dakẹ jẹ. Afẹfẹ si da, iparọrọ nla si de.

40. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ojo bẹ̃? ẹ kò ti iní igbagbọ sibẹ?

41. Ẹru si ba wọn gidigidi, nwọn si nwi fun ara wọn pe, Irú enia kili eyi, ti ati afẹfẹ ati okun gbọ́ tirẹ̀?

Mak 4