5. Nigbati o si fi ibinu wò gbogbo wọn yiká, ti inu rẹ̀ bajẹ nitori lile àiya wọn, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si nà a: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji.
6. Awọn Farisi jade lọ lojukanna lati ba awọn ọmọ-ẹhin Herodu gbìmọ pọ̀ si i, bi awọn iba ti ṣe pa a.
7. Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si kuro nibẹ̀ lọ si eti okun: ijọ enia pipọ lati Galili ati Judea wá si tọ̀ ọ lẹhin,
8. Ati lati Jerusalemu, ati lati Idumea, ati lati oke odò Jordani, ati awọn ti o wà niha Tire on Sidoni, ijọ enia pipọ; nigbati nwọn gbọ́ ohun nla ti o ṣe, nwọn tọ̀ ọ wá.
9. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn mu ọkọ̀ kekere kan sunmọ on, nitori ijọ enia, ki nwọn ki o má bà bilù u.
10. Nitoriti o mu ọ̀pọ enia larada; tobẹ̃ ti nwọn mbì ara wọn lù u lati fi ọwọ́ kàn a, iye awọn ti o li arùn.
11. Ati awọn ẹmi aimọ́, nigbàkugba ti nwọn ba ri i, nwọn a wolẹ niwaju rẹ̀, nwọn a kigbe soke, wipe, Iwọ li Ọmọ Ọlọrun.
12. O si kìlọ fun wọn gidigidi pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn.