20. Nigbati nwọn si fi i ṣẹ̀sin tan, nwọn si bọ́ aṣọ elesè àluko na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si mu u jade lọ lati kàn a mọ agbelebu.
21. Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu.
22. Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari.
23. Nwọn si fi ọti-waini ti a dàpọ mọ ojia fun u lati mu: ṣugbọn on kò gbà a.
24. Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu tan, nwọn si pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gège lori wọn, eyi ti olukuluku iba mú.
25. Ni wakati kẹta ọjọ, on ni nwọn kàn a mọ agbelebu.
26. A si kọwe akọle ọ̀ran ifisùn rẹ̀ si igberi rẹ̀ ỌBA AWỌN JU.
27. Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀.
28. Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin.
29. Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta,
30. Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá.
31. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀.