1. ATI lojukanna li owurọ, awọn olori alufa jọ gbìmọ pẹlu awọn alàgba, ati awọn akọwe, ati gbogbo ajọ ìgbimọ, nwọn si dè Jesu, nwọn si mu u lọ, nwọn si fi i le Pilatu lọwọ.
2. Pilatu si bi i lẽre, wipe Iwọ ha li Ọba awọn Ju? O si dahùn wi fun u pe, Iwọ wi i.
3. Awọn olori alufa si fi i sùn li ohun pipọ: ṣugbọn on ko dahùn kan.
4. Pilatu si tún bi i lẽre, wipe, Iwọ ko dahùn ohun kan? wò ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ.
5. Ṣugbọn Jesu ko da a ni gbolohùn kan: tobẹ̃ ti ẹnu fi yà Pilatu.