8. Nwọn si mu u, nwọn pa a, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu ọgba ajara na.
9. Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe? On o wá, yio si pa awọn oluṣọgba wọnni run, yio si fi ọgba ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn ẹlomiran.
10. Ẹnyin kò ha ti kà iwe-mimọ yi; Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ on na li o di pàtaki igun ile:
11. Eyi ni ìṣe Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa?
12. Nwọn si nwá ọ̀na ati mu u, sugbọn nwọn si bẹ̀ru ijọ enia: nitori nwọn mọ̀ pe, awọn li o powe na mọ: nwọn si fi i silẹ, nwọn lọ.
13. Nwọn si rán awọn kan si i ninu awọn Farisi, ati ninu awọn ọmọ-ẹhin Herodu, lati fi ọ̀rọ rẹ̀ mu u.
14. Nigbati nwọn si de, nwọn wi fun u pe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ bẹ̃ni iwọ kì iwoju ẹnikẹni: nitori iwọ kì iṣe ojuṣãju enia, ṣugbọn iwọ nkọ́ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ: O tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́?
15. Ki awa ki o fifun u, tabi ki a má fifun u? Ṣugbọn Jesu mọ̀ agabagebe wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? ẹ mu owo-idẹ kan fun mi wá ki emi ki o wò o.
16. Nwọn si mu u wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn si wi fun u pe, Ti Kesari ni.
17. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Ẹnu si yà wọn si i gidigidi.
18. Awọn Sadusi si tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si; nwọn si bi i lẽre, wipe,
19. Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, ti o ba si fi aya silẹ, ti kò si fi ọmọ silẹ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o si gbe iru-ọmọ dide fun arakunrin rẹ̀.
20. Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: eyi ekini si gbé iyawo, o si kú lai fi ọmọ silẹ.
21. Eyi ekeji si ṣu u lopó, on si kú, bẹ̃li on kò si fi ọmọ silẹ: gẹgẹ bẹ̃ si li ẹkẹta.
22. Awọn mejeje si ṣu u lopó, nwọn kò si fi ọmọ silẹ: nikẹhin gbogbo wọn obinrin na kú pẹlu.