2. O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin: lojukanna bi ẹnyin ti nwọ̀ inu rẹ̀ lọ, ẹnyin ó si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn rì; ẹ tú u, ki é si fà a wá.
3. Bi ẹnikẹni ba si wi fun nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi? ẹ wipe, Oluwa ni fi ṣe; lojukanna yio si rán a wá sihinyi.
4. Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ na ti a so li ẹnu-ọ̀na lode ni ita gbangba; nwọn si tú u.
5. Awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nṣe, ti ẹnyin fi ntú ọmọ kẹtẹkẹtẹ nì?
6. Nwọn si wi fun wọn gẹgẹ bi Jesu ti wi fun wọn: nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ.
7. Nwọn si fà ọmọ kẹtẹkẹtẹ na tọ̀ Jesu wá, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹ̀hin rẹ̀; on si joko lori rẹ̀.
8. Awọn pipọ si tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na: ati awọn miran ṣẹ́ ẹ̀ka igi, nwọn si fún wọn si ọ̀na.
9. Ati awọn ti nlọ niwaju, ati awọn ti mbọ̀ lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna; Olubukun li ẹniti o mbọ̀wá li orukọ Oluwa:
10. Olubukun ni ijọba ti mbọ̀wá, ijọba Dafidi, baba wa: Hosanna loke ọrun.
11. Jesu si wọ̀ Jerusalemu, ati tẹmpili. Nigbati o si wò ohun gbogbo yiká, alẹ sa ti lẹ tan, o si jade lọ si Betani pẹlu awọn mejila.
12. Ni ijọ keji, nigbati nwọn ti Betani jade, ebi si npa a:
13. O si ri igi ọpọtọ kan li òkere ti o li ewé, o wá, bi bọya on le ri ohun kan lori rẹ̀: nigbati o si wá si idi rẹ̀, ko ri ohun kan, bikoṣe ewé; nitori akokò eso ọpọtọ kò ti ito.
14. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Ki ẹnikẹni má jẹ eso lori rẹ mọ́ titi lai. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́ ọ.