Luk 8:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.

9. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Kili a le mọ̀ owe yi si?

10. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ọ̀rọ ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn miran li owe; pe ni riri, ki nwọn ki o má le ri, ati ni gbigbọ ki o má le yé wọn.

11. Njẹ owe na li eyi: Irugbin li ọ̀rọ Ọlọrun.

12. Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là.

13. Awọn ti ori apata li awọn, nigbati nwọn gbọ́, nwọn fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ na; awọn wọnyi kò si ni gbòngbo, nwọn a gbagbọ fun sã diẹ; nigba idanwò, nwọn a pada sẹhin.

14. Awọn ti o bọ sinu ẹgún li awọn, nigbati nwọn gbọ́ tan, nwọn lọ, nwọn a si fi itọju ati ọrọ̀ ati irọra aiye fun u pa, nwọn kò si le so eso asogbo.

15. Ṣugbọn ti ilẹ rere li awọn, ti nwọn fi ọkàn otitọ ati rere gbọ ọrọ na, nwọn di i mu ṣinṣin, nwọn si fi sũru so eso.

16. Kò si ẹnikẹni, nigbati o ba tàn fitilà tan, ti yio fi ohun elò bò o mọlẹ, tabi ti yio gbé e kà abẹ akete; bikoṣe ki o gbé e kà ori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọ̀ ile ki o le ri imọlẹ.

17. Nitori kò si ohun ti o lumọ́, ti a ki yio fi hàn, bẹ̃ni kò si ohun ti o pamọ́, ti a kì yio mọ̀, ti ki yio si yọ si gbangba.

18. Njẹ ki ẹnyin ki o mã kiyesara bi ẹnyin ti ngbọ́: nitori ẹnikẹni ti o ba ni, on li a o fifun; ati ẹnikẹni ti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi ti o ṣebi on ni.

Luk 8