Luk 8:33-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Nigbati awọn ẹmi èṣu si jade kuro lara ọkunrin na, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tu pũ nwọn si sure lọ si ibi bèbe sinu adagun, nwọn si rì sinu omi.

34. Nigbati awọn ti mbọ́ wọn ri ohun ti o ṣe, nwọn sá, nwọn si lọ, nwọn si ròhin ni ilu ati ni ilẹ na.

35. Nigbana ni nwọn jade lọ iwò ohun na ti o ṣe; nwọn si tọ̀ Jesu wá, nwọn si ri ọkunrin na, lara ẹniti awọn ẹmi èṣu ti jade lọ, o joko lẹba ẹsẹ Jesu, o wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ̀ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn.

36. Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ṣe ti a fi mu ẹniti o li ẹmi èṣu larada.

37. Nigbana ni gbogbo enia lati ilẹ Gadara yiká bẹ̀ ẹ pe, ki o lọ kuro lọdọ wọn; ẹ̀ru sá ba wọn gidigidi: o si bọ sinu ọkọ̀, o pada sẹhin.

Luk 8