6. Jesu si mba wọn lọ. Nigbati kò si jìn si eti ile mọ́, balogun ọrún na rán awọn ọrẹ́ si i, wipe, Oluwa, má yọ ara rẹ lẹnu: nitoriti emi kò to ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi:
7. Nitorina emi kò si rò pe emi na yẹ lati tọ̀ ọ wá: ṣugbọn sọ ni gbolohùn kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada.
8. Nitori emi na pẹlu jẹ ẹniti a fi si abẹ aṣẹ, ti o li ọmọ-ogun li ẹhin mi, mo wi fun ọkan pe, Lọ, a si lọ; ati fun omiran pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e.