1. JESU si kún fun Ẹmí Mimọ́, o pada ti Jordani wá, a si ti ọwọ́ Ẹmí dari rẹ̀ si ijù;
2. Ogoji ọjọ li a fi dán a wò lọwọ Èṣu. Kò si jẹ ohunkohun li ọjọ wọnni: nigbati nwọn si pari, lẹhinna li ebi wá npa a.
3. Eṣu si wi fun u pe, Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ fun okuta yi ki o di akara.
4. Jesu si dahùn wi fun u pe, A ti kọwe rẹ pe, Enia kì yio wà lãye nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ Ọlọrun.
5. Èṣu si mu u re ori òke giga, o si fi gbogbo ilẹ-ọba aiye hàn a ni iṣẹju kan.
6. Èṣu si wi fun u pe, Iwọ li emi o fi gbogbo agbara yi ati ogo wọn fun: gbogbo rẹ̀ li a sá ti fifun mi; ẹnikẹni ti o ba si wù mi, emi a fi i fun.
7. Njẹ bi iwọ ba foribalẹ fun mi, gbogbo rẹ̀ ni yio jẹ tirẹ.
8. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kuro lẹhin mi, Satani, nitoriti a kọwe rẹ̀ pe, Iwọ foribalẹ fun Oluwa Ọlọrun rẹ, on nikanṣoṣo ni ki iwọ ki o si ma sìn.
9. O si mu u lọ si Jerusalemu, o si gbé e le ṣonṣo tẹmpili, o si wi fun u pe, Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ lati ihinyi lọ: