Luk 24:44-53 Yorùbá Bibeli (YCE)

44. O si wi fun wọn pe, Nwọnyi li ọrọ ti mo sọ fun nyin, nigbati emi ti wà pẹlu nyin pe, A kò le ṣe alaimu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ ninu ofin Mose, ati ninu iwe awọn woli, ati ninu Psalmu, nipasẹ̀ mi.

45. Nigbana li o ṣí wọn ni iyè, ki iwe-mimọ́ ki o le yé wọn,

46. O si wi fun wọn pe, Bẹ̃li a ti kọwe rẹ̀, pe, ki Kristi ki o jìya, ati ki o si jinde ni ijọ kẹta kuro ninu okú:

47. Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ.

48. Ẹnyin si ni ẹlẹri nkan wọnyi.

49. Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalemu, titi a o fi fi agbara wọ̀ nyin, lati oke ọrun wá.

50. O si mu wọn jade lọ titi nwọn fẹrẹ̀ de Betani, nigbati o si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o sure fun wọn.

51. O si ṣe, bi o ti nsure fun wọn, a yà a kuro lọdọ wọn, a si gbé e lọ si ọrun.

52. Nwọn si foribalẹ̀ fun u, nwọn si pada lọ si Jerusalemu pẹlu ayọ̀ pipọ:

53. Nwọn si wà ni tẹmpili nigbagbogbo, nwọn mbu iyin, nwọn si nfi ibukun fun Ọlọrun. Amin.

Luk 24