8. O si wipe, Ẹ mã kiyesara, ki a má bà mu nyin ṣina: nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, ti yio mã wipe, Emi ni Kristi; akokò igbana si kù si dẹ̀dẹ: ẹ máṣe tọ̀ wọn lẹhin.
9. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gburó ogun ati idagìri, ẹ máṣe foiya: nitori nkan wọnyi ko le ṣe áìkọ́ṣẹ: ṣugbọn opin na kì iṣe lojukanna.
10. Nigbana li o wi fun wọn pe, Orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba:
11. Isẹlẹ nla yio si wà kakiri, ati ìyan ati ajakalẹ arùn; ohun ẹ̀ru, ati àmi nla yio si ti ọrun wá.
12. Ṣugbọn ṣaju gbogbo nkan wọnyi, nwọn o nawọ́ mu nyin, nwọn o si ṣe inunibini si nyin, nwọn o fi nyin le awọn oni-sinagogu lọwọ, ati sinu tubu, nwọn o mu nyin lọ sọdọ awọn ọba ati awọn ijoye nitori orukọ mi.
13. Yio si pada di ẹrí fun nyin.
14. Nitorina ẹ pinnu rẹ̀ li ọkàn nyin pe ẹ kì yio ronu ṣaju, bi ẹ o ti dahun.
15. Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọ́n, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju.
16. A o si fi nyin hàn lati ọdọ awọn õbi nyin wá, ati awọn arakunrin, ati awọn ibatan, ati awọn ọrẹ́ wá; nwọn o si mu ki a pa ninu nyin.
17. A o si korira nyin lọdọ gbogbo enia nitori orukọ mi.
18. Ṣugbọn irun ori nyin kan kì o ṣegbé.
19. Ninu sũru nyin li ẹnyin o jère ọkàn nyin.
20. Nigbati ẹnyin ba si ri ti a fi ogun yi Jerusalemu ká, ẹ mọ̀ nigbana pe, isọdahoro rẹ̀ kù si dẹ̀dẹ.
21. Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sá lọ sori òke; ati awọn ti mbẹ larin rẹ̀ ki nwọn jade kuro; ki awọn ti o si mbẹ ni igberiko ki o máṣe wọ̀ inu rẹ̀ lọ.
22. Nitori ọjọ ẹsan li ọjọ wọnni, ki a le mu ohun gbogbo ti a ti kọwe rẹ̀ ṣẹ.
23. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! nitoriti ipọnju pipọ yio wà lori ati ibinu si awọn enia wọnyi.
24. Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si dì wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo: Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún.