1. O si pa owe kan fun wọn nitori eyiyi pe, o yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ̀;
2. Wipe, Onidajọ́ kan wà ni ilu kan, ti kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti kò si ṣe ojusaju enia:
3. Opó kan si wà ni ilu na; o si ntọ̀ ọ wá, wipe, Gbẹsan mi lara ọtá mi.
4. Kò si ṣu si i nigba sã kan: ṣugbọn nikẹhin o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi emi kò tilẹ bẹ̀ru Ọlọrun, ti emi ko si ṣe ojuṣãju enia;
5. Ṣugbọn nitoriti opó yi nyọ mi lẹnu, emi o gbẹsan rẹ̀, ki o má ba fi wíwa rẹ̀ nigbakugba da mi lagãra.
6. Oluwa si wipe, Ẹ gbọ́ bi alaiṣõtọ onidajọ ti wi.
7. Ọlọrun kì yio ha si gbẹsan awọn ayanfẹ rẹ̀, ti nfi ọsán ati oru kigbe pè e, ti o si mu suru fun wọn?
8. Mo wi fun nyin, yio gbẹsan wọn kánkán. Ṣugbọn nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ́ li aiye?
9. O si pa owe yi fun awọn kan ti nwọn gbẹkẹle ara wọn pe, awọn li olododo, ti nwọn si ngàn awọn ẹlomiran:
10. Pe, Awọn ọkunrin meji goke lọ si tẹmpili lati gbadura; ọkan jẹ Farisi, ekeji si jẹ agbowode.