1. O SI wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ko le ṣe ki ohun ikọsẹ̀ má de: ṣugbọn egbé ni fun ẹniti o ti ipasẹ rẹ̀ de.
2. Iba san fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si gbé e jù sinu okun, ju ki o mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi kọsẹ̀.
3. Ẹ mã kiyesara nyin: bi arakunrin rẹ ba ṣẹ̀, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari jì i.
4. Bi o ba si ṣẹ̀ ọ li ẹrinmeje li õjọ, ti o si pada tọ̀ ọ wá li ẹrinmeje li õjọ pe, Mo ronupiwada; dari jì i.
5. Awọn aposteli si wi fun Oluwa pe, Busi igbagbọ́ wa.
6. Oluwa si wipe, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irugbin mustardi, ẹnyin o le wi fun igi sikamine yi pe, Ki a fà ọ tú, ki a si gbìn ọ sinu okun; yio si gbọ́ ti nyin.
7. Ṣugbọn tani ninu nyin, ti o li ọmọ-ọdọ, ti o ntulẹ, tabi ti o mbọ́ ẹran, ti yio wi fun u lojukanna ti o ba ti oko de pe, Lọ ijoko lati jẹun?
8. Ti kì yio kuku wi fun u pe, Pèse ohun ti emi o jẹ, si di amure, ki iwọ ki o mã ṣe iranṣẹ fun mi, titi emi o fi jẹ ti emi o si mu tan; lẹhinna ni iwọ o si jẹ, ti iwọ o si mu?