Luk 16:26-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Ati pẹlu gbogbo eyi, a gbe ọgbun nla kan si agbedemeji awa ati ẹnyin, ki awọn ti nfẹ má ba le rekọja lati ìhin lọ sọdọ nyin, ki ẹnikẹni má si le ti ọ̀hun rekọja tọ̀ wa wá.

27. O si wipe, Njẹ mo bẹ̀ ọ, baba, ki iwọ ki o rán a lọ si ile baba mi:

28. Nitori mo ni arakunrin marun; ki o le rò fun wọn ki awọn ki o má ba wá si ibi oró yi pẹlu.

29. Abrahamu si wi fun u pe, Nwọn ni Mose ati awọn woli; ki nwọn ki o gbọ́ ti wọn.

30. O si wipe, Bẹ̃kọ, Abrahamu baba; ṣugbọn bi ẹnikan ba ti inu okú tọ̀ wọn lọ, nwọn ó ronupiwada.

31. O si wi fun u pe, Bi nwọn kò ba gbọ́ ti Mose ati ti awọn woli, a kì yio yi wọn li ọkan pada bi ẹnikan tilẹ ti inu okú dide.

Luk 16