15. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọkàn nyin: nitori eyi ti a gbé niyin lọdọ enia, irira ni niwaju Ọlọrun.
16. Ofin ati awọn woli mbẹ titi di igba Johanu: lati igbana wá li a ti nwasu ijọba Ọlọrun, olukuluku si nfi ipá wọ̀ inu rẹ̀.
17. Ṣugbọn o rọrun fun ọrun on aiye lati kọja lọ, jù ki ṣonṣo kan ti ofin ki o yẹ̀.
18. Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé, ẹniti ọkọ rẹ̀ kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga.
19. Njẹ ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o nwọ̀ aṣọ elesè àluko ati aṣọ àla daradara, a si ma jẹ didùndidun lojojumọ́:
20. Alagbe kan si wà ti a npè ni Lasaru, ti nwọn ima gbé wá kalẹ lẹba ọ̀na ile rẹ̀, o kún fun õju,
21. On a si ma fẹ ki a fi ẹrún ti o ti ori tabili ọlọrọ̀ bọ silẹ bọ́ on: awọn ajá si wá, nwọn si fá a li õju lá.
22. O si ṣe, alagbe kú, a si ti ọwọ́ awọn angẹli gbé e lọ si õkan-àiya Abrahamu: ọlọrọ̀ na si kú pẹlu, a si sin i;
23. Ni ipo-oku li o gbé oju rẹ̀ soke, o mbẹ ninu iṣẹ oró, o si ri Abrahamu li òkere, ati Lasaru li õkan-àiya rẹ̀.