35. Nitorina kiyesi i, ki imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ki o máṣe di òkunkun.
36. Njẹ bi gbogbo ara rẹ ba kun fun imọlẹ, ti ko li apakan ti o ṣokunkun, ara rẹ, gbogbo ni yio kun fun imọlẹ, bi igbati fitila ba fi itanṣan rẹ̀ fun ọ ni imọlẹ.
37. Bi o si ti nwi, Farisi kan bẹ̀ ẹ ki o ba on jẹun: o si wọle, o joko lati jẹun.
38. Nigbati Farisi na si ri i, ẹnu yà a nitoriti kò kọ́ wẹ̀ ki o to jẹun.
39. Oluwa si wi fun u pe, Ẹnyin Farisi a ma fọ̀ ode ago ati awopọkọ́; ṣugbọn inu nyin kún fun irẹjẹ iwa-buburu.
40. Ẹnyin alaimoye, ẹniti o ṣe eyi ti mbẹ lode, on kọ́ ha ṣe eyi ti mbẹ ninu pẹlu?
41. Ki ẹnyin ki o kuku mã ṣe itọrẹ ãnu ninu ohun ti ẹnyin ni; si kiyesi i, ohun gbogbo li o di mimọ́ fun nyin.
42. Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin a ma san idamẹwa minti, ati rue, ati gbogbo ewebẹ̀, ṣugbọn ẹnyin gbojufò idajọ ati ifẹ Ọlọrun: wọnyi li ẹnyin iba ṣe, ẹ kì ba si ti fi ekeji silẹ laiṣe.
43. Egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin fẹ ipò-ọlá ninu sinagogu, ati ikí-ni li ọjà.
44. Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe, ati ẹnyin Farisi, agabagebe! nitoriti ẹnyin dabi isa okú ti kò hàn, awọn enia ti o si nrìn lori wọn kò mọ̀.
45. Nigbana li ọkan ninu awọn amofin dahùn, o si wi fun u pe, Olukọni, li eyi ti iwọ nwi nì iwọ ngàn awa pẹlu.