7. Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile.
8. Ati ni ilukilu ti ẹnyin ba wọ̀, ti nwọn ba si gbà nyin, ẹ jẹ ohunkohun ti a ba gbé kà iwaju nyin:
9. Ẹ si mu awọn alaisan ti mbẹ ninu rẹ̀ larada, ki ẹ si wi fun wọn pe, Ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin.
10. Ṣugbọn ni ilukilu ti ẹnyin ba si wọ̀, ti nwọn kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba si jade si igboro ilu na, ki ẹnyin ki o si wipe,
11. Ekuru iyekuru ilu nyin ti o kù si wa lara, a gbọn ọ silẹ fun nyin: ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin.
12. Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ni ijọ na, jù fun ilu na lọ.
13. Egbé ni fun iwọ, Korasini! Egbé ni fun iwọ, Betsaida! nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin, ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai, nwọn iba si joko ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru.
14. Ṣugbọn yio san fun Tire on Sidoni nigba idajọ jù fun ẹnyin lọ.
15. Ati iwọ, Kapernaumu, a o ha gbe ọ ga de oke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ de ipo-oku.
16. Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi.
17. Awọn adọrin na si fi ayọ̀ pada, wipe, Oluwa, awọn ẹmi èṣu tilẹ foribalẹ fun wa li orukọ rẹ.
18. O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá.
19. Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara.
20. Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun.
21. Ni wakati kanna Jesu yọ̀ ninu Ẹmi Mimọ́ o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ, Baba, Oluwa ọrun on aiye, pe, iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro lọdọ awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ: bẹ̃ni, Baba, bẹ̃li o sá yẹ li oju rẹ.
22. Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ ẹniti Ọmọ iṣe, bikoṣe Baba; ati ẹniti Baba iṣe, bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti o ba si wù Ọmọ lati fi i hàn fun.
23. O si yipada si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li apakan, o ni, Ibukún ni fun ojú ti nri ohun ti ẹnyin nri: