Egbé ni fun iwọ, Korasini! Egbé ni fun iwọ, Betsaida! nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin, ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai, nwọn iba si joko ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru.