13. Wundia ni ki o fẹ́ li aya fun ara rẹ̀.
14. Opó, tabi obinrin ikọsilẹ, tabi ẹni-ibàjẹ́, tabi panṣaga, wọnyi ni on kò gbọdọ fẹ́: bikoṣe wundia ni ki o fẹ́ li aya lati inu awọn enia rẹ̀.
15. Bẹ̃ni ki o máṣe bà irú-ọmọ rẹ̀ jẹ́ ninu awọn enia rẹ̀: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà a simimọ́.
16. OLUWA si sọ fun Mose pe,
17. Sọ fun Aaroni pe, Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ rẹ ni iran-iran wọn, ti o ní àbuku kan, ki o máṣe sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀.
18. Nitoripe gbogbo ọkunrin ti o ní àbuku, ki o máṣe sunmọtosi: ọkunrin afọju, tabi amukun, tabi arẹ́mu, tabi ohun kan ti o leke,