Lef 21:12-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Bẹ̃ni ki o máṣe jade kuro ninu ibi mimọ́, bẹ̃ni ki o máṣe bà ibi mimọ́ Ọlọrun rẹ̀ jẹ́, nitoripe adé oróro itasori Ọlọrun rẹ̀ mbẹ lori rẹ̀: Emi li OLUWA.

13. Wundia ni ki o fẹ́ li aya fun ara rẹ̀.

14. Opó, tabi obinrin ikọsilẹ, tabi ẹni-ibàjẹ́, tabi panṣaga, wọnyi ni on kò gbọdọ fẹ́: bikoṣe wundia ni ki o fẹ́ li aya lati inu awọn enia rẹ̀.

15. Bẹ̃ni ki o máṣe bà irú-ọmọ rẹ̀ jẹ́ ninu awọn enia rẹ̀: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà a simimọ́.

16. OLUWA si sọ fun Mose pe,

17. Sọ fun Aaroni pe, Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ rẹ ni iran-iran wọn, ti o ní àbuku kan, ki o máṣe sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀.

18. Nitoripe gbogbo ọkunrin ti o ní àbuku, ki o máṣe sunmọtosi: ọkunrin afọju, tabi amukun, tabi arẹ́mu, tabi ohun kan ti o leke,

19. Tabi ọkunrin ti iṣe aṣẹ́sẹ̀, tabi aṣẹ́wọ,

20. Tabi abuké, tabi arará, tabi ẹniti o ní àbuku kan li oju rẹ̀, tabi ti o ní ekuru, tabi ipẹ́, tabi ti kóro rẹ̀ fọ́;

21. Ẹnikẹni ti o ní àbuku ninu irúọmọ Aaroni alufa kò gbọdọ sunmọtosi lati ru ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: on li àbuku; kò gbọdọ sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀.

Lef 21